Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 349: Mo Fẹ́ Máa Sọ Ìtàn Náà

I Love To Tell The Story

Mo fẹ́ máa sọ ìtàn náà
T' ohun aírí l' òkè,
Ti Jésù àt' ògó Rẹ,
Jésù oùn ìfẹ́ Rẹ;
Mo fẹ́ máa sọ ìtàn náà
'Tòrí mo mọ̀ l' oòtọ́,
Ó tẹ́ ìfẹ́ mi lọ́rùn,
ju ohunkóhun lọ.

Mo fẹ́ máa sọ ìtàn náà,
N ó sì sọ ọ nínú ògó,
N ó sọ ìtàn àtijọ́
Ti Jésù oùn 'fẹ́ Rẹ.

Mo fẹ́ máa sọ ìtàn náà
Ó yànílenú ju
Gbogb' ohun àago náà lọ,
Tí a fi ń là àlá;
Mo fẹ́ máa sọ ìtàn náà,
Ó ṣe fún mi púpọ̀,
'Tòrí ìdí èyí náà
Ni mo fi ń sọ fún ọ.

Mo fẹ́ máa sọ ìtàn náà,
N ó sì sọ ọ nínú ògó,
N ó sọ ìtàn àtijọ́
Ti Jésù oùn 'fẹ́ Rẹ.

Mo fẹ́ máa sọ ìtàn náà,
Ó dùn láti máa sọ ọ,
'Gbàkúùgbà tí mo bá ń sọ ọ
Ni ó túbọ̀ ń dùn sí i;
Mo fẹ́ máa sọ ìtàn náà,
'Tòr' àwọn míì kò 'tíì
Gbọ́ iṣẹ́ ìgbàlà náà,
Láti 'nú 'wé mímọ́.

Mo fẹ́ máa sọ ìtàn náà,
N ó sì sọ ọ nínú ògó,
N ó sọ ìtàn àtijọ́
Ti Jésù oùn 'fẹ́ Rẹ.

Mo fẹ́ máa sọ ìtàn náà,
F' àwọn t' ó mọ̀ jù lọ
Ó dàb' ẹ̀bí àt' oúngbẹ
Láti gbọ́ọ b' àwọn míì;
'Gbà mo bá wọ 'nú ògó
N ó kọrin títun náà,
Yóò jẹ́ ìtàn àtijọ́.
Tí mo ti fẹ́ máa sọ.

Mo fẹ́ máa sọ ìtàn náà,
N ó sì sọ ọ nínú ògó,
N ó sọ ìtàn àtijọ́
Ti Jésù oùn 'fẹ́ Rẹ.