Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 348: Ìfẹ́ Kíkún Tí Kò L' Òpin

Immortal Love Forever Full

Ìfẹ́ kíkún tí kò l' òpin,
T' ó ń san fún wa l' ọ̀fẹ́ẹ́;
T' a ń pín fún ni, síbẹ̀ t' ó kún,
Òkun tí kò lè gbẹ.

A kò lè gòkè ọ̀run lọ
Fà Jésù wá s' ayé:
Lásán l' àn wá inú ibú
F' Ẹni bù kò lè bọ́.

Ṣùgbọ́n Ó tara, Ó l' àánú,
Ìránwọ́ Rẹ dájú,
Ìgbàgbọ́ l' òkè Olífì
Ìfẹ́ ní Galílì.

Ìmúláradà aṣọ Rẹ
Wà ní àrọ̀wọ́tọ́,
A ń fọwọ́ kan An láàrín àgbo,
A mú wa láradá.

Nípasẹ̀ Rẹ l' àwa ewé
Gbà àdúrà dídan;
Ẹ̀ẹ́mí 'kẹyìn àwọn òkú
Kún fún orúkọ Rẹ.

Ọlọ́run, Olúwa, gbogbo
Ohun t' ó wù k' a jẹ́,
Tire ni wa, a gbọ́hùn Rẹ,
Ẹ̀mí Rẹ ni wọ́n wà.