Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 347: N' Nú Dààmú, Ọ̀pọ̀ Ènìyàn
Long Upon The Mountains
N' nú dààmú, ọ̀pọ̀ ènìyàn
Fọ́nká orí òkè náà;
Wọ́n rìn nín' àṣàlẹ́ 'pọ́njú,
Wọ́n ti là 'ṣòro kọjá,
Báyìí ìpè dùn fún 'kọjá,
Jẹ̀jẹ̀ l' ohùn 'kìlọ̀ náà;
Ìdápọ̀ 'fẹ́ àt' ìgbàgbọ́,
Sọ fún wọn kí wọ́n máa yọ.
Wọ́n ń wá ìmọ́lẹ̀ òtítọ́,
Nísiyìí bí wọ́n ti ń lọ;
Wọ́n ń pa òfin mẹ́wàá mọ́,
Mímọ́, àt' oòtọ́ ni wọn.
Ọ̀rọ̀ ìyè ni oúnjẹ wọn,
Ọ̀wọ́n l' adùn ọ̀rọ̀ náà;
Wọ́n tẹ̀lé 'ṣiṣẹ́ Ọ̀gá wọn
Àní wọ́n tẹrìba fún-Un.
Nínú ìmọ́lẹ̀ àt' ẹwà,
Nínú ìlú dídan ni;
Láìpẹ́ wọ́n yóò wọ 'nú 'lú náà,
Láti pín nín' ògó rẹ̀.
Níbẹ̀ wọ́n di ẹni mímọ́,
Kò s' ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ikú,
Níbẹ̀ kò ní sí ẹkún mọ́,
Ilé ayérayé ni.
Láìpẹ́ yóò dé l' àwọ̀sánmọ̀
Àwọn àyànfẹ́ yóò jíǹdé
Àwọn àyànfẹ́ yóò jíǹdé,
Orin wọn yóò gb' ọ̀run kan
Àwa ń dúró dé bíbọ̀ Rẹ,
Wá kankan, Olùgbàlà;
'Rètí ògó ń mú 'nú wa dùn,
Kó àyànfẹ́ Rẹ rè 'lé.