Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 346: Mo R' Ẹnìkan T' Ààrẹ̀ Ti Mú
I Saw One Weary Sad and Torn
Mo r' ẹnìkan t' ààrẹ̀ ti mú,
T' ó ń tẹ̀síwájú n' àjò rẹ̀;
Ó pẹ́ t' ó ti ń r' àgbélébùú,
Ó ń wá ọjọ́ alábùkún.
Ọ̀pọ̀ 'bànújẹ́ àt' ìyà,
L' ó wà ní gbogbo ojú rẹ̀
Mo bèèrè kíl' ó fún l' okùn?
Ó dáhùn "ìrètí 'búkún".
Mo r' ẹnìkan t' ó ní 'gboyà,
Pẹ̀lú idà àti àsà;
Ó ja pẹ̀lú ìfaradà,
Láti gb' adé 'yè àìlópin
Lórí 'jà náà ààrẹ̀ dé bá a,
Síbẹ̀ kò sọ àwàwí kan;
Mo bèèrè kíl' ó fún un l' okùn?
Ó dáhùn "ìrètí 'búkún"
Ẹnìkan wà t' ó kọ àwọn,
Ọ̀rẹ́ ìgbà ewé sílẹ̀;
Pẹ̀lú ọrọ̀ àti ọlá,
Láti gb' adé 'yè àìlópin.
Lórí 'jà náà ààrẹ̀ dé bá a,
Síbẹ̀ kò ṣe àwàwí kan;
Mo bèèrè kíl' ó fún un l' okùn?
Ó dáhùn "ìrètí 'búkún"
Bí ẹ̀rọ, a ń rìn 'rìn-àjò,
L' ayé ewu àti ẹ̀ṣẹ̀;
Nínú ọ̀tẹ̀, ìkórìrà
Tàbí nín' ojìjì ikú.
Títí Ọba wa yóò fi dé
Láti k' àwọn 'gbèkún lọ 'lé
Kíl' ó fún gbogbo wọn l' okùn?
"Ìrètí ìbùkún" nìkan.