Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 343: Bí Mo Ti Ń Lọ, Mo Bèèrè Pé
How Far From Home?
Bí mo ti ń lọ, mo bèèrè pé,
Olùṣọ́ ilé jìnà bí?
Ó ní, Órù bù kọjá tán
Ilé sì fẹ́rẹ̀ mọ́.
Má sọkún mọ́, tẹra m' àrẹ̀.
Ìràwọ̀ Ìrètí yóò tọ́ ọ
Títí o ó fi wọ 'nú 'mọ́lẹ̀.
Ní ọjọ́ àìlópin.
Mo bí ọmọ-ogun léèrè,
Orin yí lo fi dáhùn pé,
Èmi ó ja pẹ̀lú 'gboyà,
Ogun náà kò ní pẹ́
Má sọkún mọ́, ṣàá faradà
Ogun náà títí y' ó parí
Ó dá wa lójú pé ère.
Ń bẹ lẹ́yìn ìṣẹ́gun
Mo tún bèèrè; ó dàbí pé
Ayé àt' òkun dáhùn pé,
Ìgbà bù kọj' ayérayé
Sì sún mọ́ ìtòsí,
Nítorí náà má sọkún mọ́,
Àwọn àmín 'kìlọ̀ ń pọ̀ sí i,
Gbogbo ẹ̀dá l' ó ń kẹ̀rora
Láti gbọ́ ìpè náà.
Ilé kò jìnà! èrò yìí
L' ó ń mú inú arìn-àjò yọ;
Òun l' ó ń mú 'simi b' aláàrẹ̀,
T' ó sì ń n' omijé nù,
Má sọkún mọ́ tòr' a ó padé,
Níbi t' a kì yóò ṣako mọ́
Ìyà kọjá, ayọ̀ sì kún,
Ní ilé Bàbá wa.