Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 341: Ilé Kan Wà Lẹ́yìn Odò
There's A Land Beyond The River
Ilé kan wà lẹ́yìn odò,
Ẹwà rẹ̀ wà títí ayé;
Ìgbàgbọ́ nìkan l' ó lè sìn wa dé 'bẹ̀,
Ẹsẹ̀ ò gb' èjì l' ọ̀nà náà
Níbẹ̀ l' a ó b' àwọn àìkú gbé;
'Gb' aago wúrà bá lù fún ọ àt' èmi.
O kò gbọ́ b' aago náà tí ń dún?
O kò gbọ́ b' ángẹ́lì tí ń kọrin?
Orin ògó, Alélúyà jubílì,
N' ilé ayọ̀ ayérayé,
Lẹ́yìn òkè odò dídan náà;
'Gb' aago wúrà bá lù fún ọ àt' èmi.
Kò ní sí ẹ̀ṣẹ̀ tàb' àrọ̀,
Ní ilé ayọ̀ tí a ń lọ
Gb' okò wa bá rẹ̀fò kọj' òkun dídan;
Kík' ayọ̀, búkún ikẹ́?
Bàbá wa nìkan ni a ó mọ̀;
'Gb' aago wúrà bá lù fún ọ àt' èmi.
O kò gbọ́ b' aago náà tí ń dún?
O kò gbọ́ b' ángẹ́lì tí ń kọrin?
Orin ògó, Alélúyà jubílì,
N' ilé ayọ̀ ayérayé,
Lẹ́yìn òkè odò dídan náà;
'Gb' aago wúrà bá lù fún ọ àt' èmi.
Nígbà tí ọjọ́ wa bá pín,
Gbà t' oòrùn ikú bá mú wa;
Gbà tí Ẹlẹ́mìí bá tẹ́wọ́ gbà ẹ̀mí,
Kò ní sí ìbànújẹ́ mọ́;
A ó dé ilé ògó dídan,
'Gb' aago wúrà bá lù fún ọ àt' èmi.
O kò gbọ́ b' aago náà tí ń dún?
O kò gbọ́ b' ángẹ́lì tí ń kọrin?
Orin ògó, Alélúyà jubílì,
N' ilé ayọ̀ ayérayé,
Lẹ́yìn òkè odò dídan náà;
'Gb' aago wúrà bá lù fún ọ àt' èmi.