Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 340: Ilé Mi L' Ọ̀run Kún F' Ẹwà
I'm Going Home
Ilé mi l' ọ̀run kún f' ẹwà
Ìrora kò lè wọ ibẹ̀;
Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tayọ t' oòrùn,
T' èmi ni ilé ògó náà.
Èmi ń rè 'lé, èmi ń rè 'lé,
Èmi ń rè 'lé, ìlú àìkú
Kò s' ikú mọ́, kò s' ikú mọ́,
Èmi ń rè 'lé, ìlú àìkú.
A kọ́lé Bàbá mi s' òkè
Gíga ju àwọn 'ràwọ̀ lọ,
Gbà m' bá bọ́ nú ẹ̀wọ̀n ẹ̀ṣẹ̀,
Il' ẹwà náà yóò di tèmi.
Èmi ń rè 'lé, èmi ń rè 'lé,
Èmi ń rè 'lé, ìlú àìkú
Kò s' ikú mọ́, kò s' ikú mọ́,
Èmi ń rè 'lé, ìlú àìkú.
K' àwọn míì máa kọ́lé síhìn,
T' iná àt' ìgbì lè bàjẹ́;
Yóò jẹ́ ayọ̀ mi láti ní
Ilé t' èmi l' ẹ̀bá ìtẹ́
Èmi ń rè 'lé, èmi ń rè 'lé,
Èmi ń rè 'lé, ìlú àìkú
Kò s' ikú mọ́, kò s' ikú mọ́,
Èmi ń rè 'lé, ìlú àìkú.