Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 34: Olúwa Ọjọ́ T' Ó Fún Wa Pín

The Day Thou Gavest

Olúwa ọjọ́ t' Ó fún wa pín
Òkùnkùn sì dé l' àṣẹ Rẹ̀;
'Wọ l' akọrin òwúrọ̀ wa sì,
Ìyìn Rẹ yóò m' alẹ́ wa dùn.

A dúpẹ́ tí ìjọ Rẹ kò ń' sùn,
B' ayé tí ń' yí lọ s' ìmọ́lẹ̀,
Ó sì ń' ṣọ́nà ní gbogbo ayé
Kò sí sìmí tọ̀sán-tọ̀ru

B' ilẹ̀ sì tí ń' mọ́ lọjọ́ọjúmọ́
Ní orílẹ̀ àt' eékùsú
Ohùn àdúrà kò dákẹ́ rí,
Bẹ́ẹ̀ l' orin ìyìn kò dẹ́kun.

Bẹ́ẹ̀ Olúwa, Ìjọba Rẹ kò
Ní parẹ́ bí 'jọba ayé;
Ó dúró, Ó sì ń' ṣe àkóso,
Tít' ẹ̀dá Rẹ yóò jubà Rẹ̀.