Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 339: Àn Sọ̀rọ̀ Ilé 'Búkún Ni
We Speak Of The Realms Of The Blest
Àn sọ̀rọ̀ ilé 'búkún ni,
Ilé dídan t' ó kún f' ẹwà
'Gbà gbogbo l' a ń sọ t' ògó rẹ̀,
Yóò ti dùn tó láti dé 'bẹ̀!
A ń sọ̀rọ̀ Ìtà wúrà rẹ̀,
Ọ̀ṣọ́ odì rẹ̀ tí kò l' ẹgbẹ́;
Adùn rẹ̀ kò ṣeé f' ẹnu sọ
Yóò ti dùn tó láti dé 'bẹ̀!
A ń sọ 'pé ẹ̀ṣẹ̀ kò sí níbẹ̀!
Kò sí ààpọ̀n tàb' ìbànújẹ́
Pẹ̀lú wàhálà níhìn yí;
Yóò ti dùn tó láti dé 'bẹ̀!
A ń sọ̀rọ̀ ìsìn ìfẹ́ rẹ̀,
Ti àgbádá t' àwọn Mímọ́ ń wọ
Ìjọ àkọ́bí rí òkè
Yóò ti dùn tó láti dé 'bẹ̀!
Ìbànújẹ́ wa ti d' òpin
Gb' ọ̀rọ̀ Rẹ jí wa, t' a sì rí
Ìlú mímọ́ ń sọ̀kalẹ̀ wá.
Ta a ṣe l' ọ̀ṣọ́ f' Olúwa rẹ̀
Ìlú mímọ́ t' ó sì l' ẹwà,
Ìbànújẹ́ kò lè dé 'bẹ̀;
Ìwà ìkà, ẹ̀ṣẹ̀ kò sí;
Ojìj' ibi kò sí níbẹ̀.
Jọ̀ọ́ Olúwa lọ́nàkọ́nà
Ṣe mi yẹ fún ilé Rẹ ọ̀run;
Láìpẹ́ èmi náà yóò mọ̀
B' ó ti dùn tó láti dé 'bẹ̀!
'Gbà náà a ó yàn nín' ọlá ńlá,
Nín' ògó dídan t' ó kún f' ẹwà
Pẹ̀l' àwọn mímọ́ àt' ángẹ́lì,
Jésù ni yóò jọba níbẹ̀.