Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 338: Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àìmọ̀yè

Ten Thousand Times Ten Thousand

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àìmọ̀yè.
Wọ́n wọ aṣọ àlà.
Ogun àwọn t' a a rà padà
wọ́n kún bí 'mọ́lẹ̀ náà
Ìjà wọn pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀,
Àti 'kú ti parí,
Ẹ sì 'lẹ̀kún wúrà sílẹ̀
Fún àwọn aṣẹ́gun.

Ìró Alélúyà wọn
Lo gb' ayé, ọ̀run kan
Ìró ẹgbẹẹgbẹ̀rún Hárpù
Ń dún pé ṣẹ́gun dé tán,
Ọjọ́ t' a a ṣẹ̀dá ayé
'Ta a dá orílẹ̀-èdè
Ẹkún ayọ̀ ta a fi fún wọn
'Pa ìbànújẹ́ rẹ̀.

A! ayọ̀, t' a a kò lè sọ
Lẹ́tí bèbè Kenan!
Ìdápọ̀ ńlá wo lo tó yìí
Ibi t' a a kì í pínyà
Ojú tó kún f' ẹkún rí
Yóò tàn 'mọ́lẹ̀ ayọ̀
Kì yóò sí aláìní bàbá
Opó kì yóò sí mọ́.

Mú 'gbàlà ńlá Rẹ tún wá,
Od' àgùtàn ta a pa,
K' orúkọ àwọn àyànfẹ́,
F' agbára Rẹ jọba!
Wá, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè,
Ààyún ń ṣe oúndé Rẹ;
Wá fi àmín 'lérí Rẹ hàn;
Wá Olùgbàlà wa.