Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 337: Mímọ́, Mímọ́, L' Àwọn Ángẹ́lì Ń Kọ

Holy, Holy Is What the Angels Sing

Àwọn Ogun Ọ̀run ń kọrin
tí ẹ̀dá kan kò gbọ́ rí,
Níbẹ̀ ni àwọn ángẹ́lì;
ń kọrin yìn Od' àgùtàn;
Ohùn wọn ja gòòrò, ó sì dùn
Mo ní ì' etí púpọ̀
A bá lè túbọ̀ dà bí wọn
'gbà t' a a ń sìn Jésù níhìn.

Mímọ́, Mímọ́, l' àwọn ángẹ́lì ń kọ
Èmi yóò ṣe ránwọ́ kí odè ọ̀run hó f' ayọ̀,
Gbà mo bá ń kọrin ìràpadà
Wọ́n ó p' ẹnu mọ́
Tòr' àwọn ángẹ́lì kò lè mọ̀ ayọ̀ 'gbàlà wa

Ṣùgbọ́n èmi ń gbọ́
àwọn ohùn orin dídùn míràn
Sí Ẹni tí ó rà wa padà;
Ní orin tí wọ́n ń kọ
A ti dé ilé ẹwà náà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìṣòro
Ó ti fọ aṣọ wa mọ́ funfun
láù nínú odò tí ń san.

Mímọ́, Mímọ́, l' àwọn ángẹ́lì ń kọ
Èmi yóò ṣe ránwọ́ kí odè ọ̀run hó f' ayọ̀,
Gbà mo bá ń kọrin ìràpadà
Wọ́n ó p' ẹnu mọ́
Tòr' àwọn ángẹ́lì kò lè mọ̀ ayọ̀ 'gbàlà wa

Àwọn Ángẹ́lì ń gbọ́ lásán ni
Wọ́n kò lè kọ n' nú rẹ̀
B' irọ̀ ọ̀pọ̀ odò ṣíṣan,
L' orin ẹn' ìràpadà;
Wọ́n ń kọ nípa ìṣòro ìjà àti ìṣẹ́gun wọn
Wọ́n ń yìn Olùgbàlà t' ó
Wí fún wọn pé
"ẹ kú 'ṣe".

Mímọ́, Mímọ́, l' àwọn ángẹ́lì ń kọ
Èmi yóò ṣe ránwọ́ kí odè ọ̀run hó f' ayọ̀,
Gbà mo bá ń kọrin ìràpadà
Wọ́n ó p' ẹnu mọ́
Tòr' àwọn ángẹ́lì kò lè mọ̀ ayọ̀ 'gbàlà wa

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kì í
ṣe ángẹ́lì, síbẹ̀
Mo mọ̀ pé n ó dàpọ̀ mọ́
Ẹgbẹ́ t' ángẹ́lì kò lè wọ
N ó k' orin nípa Olùgbàlà
T' ó kú ní Kalfari
Níbi t' ó ti fòríjì mi, t' Ó sì
Sọ mi d' ọmìnira

Mímọ́, Mímọ́, l' àwọn ángẹ́lì ń kọ
Èmi yóò ṣe ránwọ́ kí odè ọ̀run hó f' ayọ̀,
Gbà mo bá ń kọrin ìràpadà
Wọ́n ó p' ẹnu mọ́
Tòr' àwọn ángẹ́lì kò lè mọ̀ ayọ̀ 'gbàlà wa