Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 336: F' Àwọn Ènìyàn Rẹ

For All The Saints

F' àwọn ènìyàn Rẹ t' ó lọ simi,
Àwọn tí ó f' ìgbàgbọ́ jẹ́wọ́ Rẹ
Ka a yìn orúkọ Rẹ, Olùgbàlà,
Alélúyà! Alélúyà!

Ìwọ l' àpáta wọn àt' odì wọn,
Ìwọ ni Balógun wọn, l' ojú 'jà,
Ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ òkùnkùn wọn.
Alélúyà! Alélúyà!

Jẹ́ k' àwọn ọmọ-ogun Rẹ l' ayé.
Jagun ní tòótọ́ b' àwọn tí 'gbà ni;
Kí wọ́n lè gbà adé ògó bí wọn.
Alélúyà! Alélúyà!

Gbàt' ìjà bá ń gbóná, tí ogun ń le,
A dàbí ẹni ń gb' orin ayọ̀ wọn;
Ìgboyà a sì dé, àt' agbára.
Alélúyà! Alélúyà!

Lát' òpin ilẹ̀, lát' òpin òkun,
Ọgọ́lọ́gọ̀ ń rọ̀ wọ 'bodè pearli;
Wọ́n ń yìn Bàbá, Ọmọ àti Ẹ̀mí
Alélúyà! Alélúyà!