Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 335: Níhìn in L' Àwa Ń Jẹ 'Ròrà

Here We Suffer Grief And Pain

Níhìn-in l' àwa ń jẹ 'ròrà,
Níhìn-in ni a máa ń pínyà;
L' ọ̀run, kò sí 'pínyà.

A! bí ó ti dùn tó!
Dùn tó, dùn tó, dùn tó!
A! bí ó ti dùn tó!
'Gbà t' a a kì ó pínyà mọ́!

Àwọn t' ó fẹ́ràn Jésù,
Wọ́n ó lọ s' òkè ọ̀run,
Lọ b' àwọn t' ó ti lọ.

A! bí ó ti dùn tó!
Dùn tó, dùn tó, dùn tó!
A! bí ó ti dùn tó!
'Gbà t' a a kì ó pínyà mọ́!

Ọmọdé yóò wà níbẹ̀,
T' ó wá Ọlọ́run l' ayé;
Ní gbogbo 'lé ẹ̀kọ́.

A! bí ó ti dùn tó!
Dùn tó, dùn tó, dùn tó!
A! bí ó ti dùn tó!
'Gbà t' a a kì ó pínyà mọ́!

Olùkọ́, bàbá, ìyá,
Wọ́n ó padé níbẹ̀ náà;
Wọ́n kì ó pínyà mọ́.

A! bí ó ti dùn tó!
Dùn tó, dùn tó, dùn tó!
A! bí ó ti dùn tó!
'Gbà t' a a kì ó pínyà mọ́!

Bí a ó ti yọ pọ̀ tó!
'Gbà t' a a bá r' Olùgbàlà;
Ní orí ìtẹ́ Rẹ!

A! bí ó ti dùn tó!
Dùn tó, dùn tó, dùn tó!
A! bí ó ti dùn tó!
'Gbà t' a a kì ó pínyà mọ́!

Níbẹ̀ l' a ó kọrin ayọ̀
Títí ayé àìlópin,
L' a ó máa yìn Jésù

A! bí ó ti dùn tó!
Dùn tó, dùn tó, dùn tó!
A! bí ó ti dùn tó!
'Gbà t' a a kì ó pínyà mọ́!