Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 333: Ilé Ayọ̀ Kan Wà
There Is A Happy Land
Ilé ayọ̀ kan wà, Ní òkèèrè;
Níb' àwọn mímọ́ wà;
Wọ́n ń rán b' oòrùn
A, wọ́n ń kọrin dídùn,
Yíyẹ l' Olùgbàlà wa,
Gb' ohùn ìyìn Rẹ ga.
Ẹ yìn láéláé.
Wá s' ilé ayọ̀ ni, Wá, wá kankan;
Ẹ ó ṣe ṣiyèméjì?
Ẹ ṣe ń dúró?
A, ayọ̀ wa yóò kún
A ó bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀;
A ó máa bá Ọ gbé,
Títí láéláé.
Gbogbo ojú yóò dán n' ilé ayọ̀;
Lábẹ́ 'tọ́jú Bàbá,
'Fẹ́ kò lè kú;
Gbà 'jọba Rẹ bá dé
Àwọn àyànfẹ́ yóò gbà
Ilé ògó dídan
Títí láéláé.