Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 332: Ilẹ̀ Kan Wà T' Ó Dára Jùlọ

There's A Land That Is Fairer Than Day

Ilẹ̀ kan wà t' ó dára jùlọ,
A lè f' ìgbàgbọ́ rí i l' òkèèrè
N' tòrí Bàbá wa dúró lọ̀nà,
Láti pèsè búgbé fún wa n' bẹ̀

Ní dídùn... Nígbòòṣe
A ó padé l' èbúté rere náà;
Ní dídùn... nígbòòṣe,
A ó padé l' èbúté rere náà.

A ó kọrin l' èbúté dídan náà
Orin dídùn t' àwọn ta a búkún
Kò ní sí ń bànújẹ́ f' ọkàn wa
Tàb' ẹ̀dùn fún 'búkún t' ìsimi.

Ní dídùn... Nígbòòṣe
A ó padé l' èbúté rere náà;
Ní dídùn... nígbòòṣe,
A ó padé l' èbúté rere náà.

Sí Bàbá wa olóore ọ̀run
L' àwa yóò máa kọ orin ìyìn,
Fún ẹ̀bùn ìfẹ́ Rẹ t' ó lògó,
Àt' ìbùkún tí ń m' ayé wa mọ́.

Ní dídùn... Nígbòòṣe
A ó padé l' èbúté rere náà;
Ní dídùn... nígbòòṣe,
A ó padé l' èbúté rere náà.