Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 331: A Ó Padé Lẹ́tí Odò?

Shall We Gather At The River?

A ó padé lẹ́tí odò,
T' ẹsẹ̀ ángẹ́lì ti tẹ̀;
T' ó mọ́ gáárá bí Kristálì,
Lẹ́bàá ìtẹ́ Ọlọ́run.

A ó padé lẹ́tí odò
Odò dídan, odò dídan náà,
Pẹ̀l' àwọn mímọ́ lẹ́bàá odò,
T' ó ń san lẹ́bàá ìtẹ́ ni

Lẹ́tí bèbè odò náà yìí,
Pẹ̀l' Olùṣ'-àgùtàn wa,
A ó máa rìn, a ó máa sìn ín
Bá a tí ń tẹ̀lé 'pàṣẹ Rẹ.

A ó padé lẹ́tí odò
Odò dídan, odò dídan náà,
Pẹ̀l' àwọn mímọ́ lẹ́bàá odò,
T' ó ń san lẹ́bàá ìtẹ́ ni

K' a a tó dé odò dídan náà,
A ó s' ẹrù wa kalẹ̀;
Oor'-ọ̀fẹ́ Rẹ yóò gbà wá là,
Òun yóò sì dé wa l' adé.

A ó padé lẹ́tí odò
Odò dídan, odò dídan náà,
Pẹ̀l' àwọn mímọ́ lẹ́bàá odò,
T' ó ń san lẹ́bàá ìtẹ́ ni

A fẹ́ẹ́ dé odò dídan náà,
'Rìn-àjò wa fẹ́rẹ̀ pín;
Ọkàn wa fẹ́rẹ̀ kún f' orin
Ayọ̀ àt' àlàáfíà.

A ó padé lẹ́tí odò
Odò dídan, odò dídan náà,
Pẹ̀l' àwọn mímọ́ lẹ́bàá odò,
T' ó ń san lẹ́bàá ìtẹ́ ni