Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 330: Ohun Ògó Rẹ L' Àn Rọ́yìn

Glorious Things Of Thee Are Spoken

Ohun ògó rẹ l' àn rọ́yìn,
Síónì, ìlú Ọlọ́run,
Ẹni t' ọ̀rọ̀ Rẹ kì í t' àṣẹ
L' ó dá ọ fún 'búgbé Rẹ
'Pìlẹ̀ rẹ ń bẹ lór' Àpáta,
Kín ni lè mí 'simi rẹ?
'A f' odì ìgbàlà ká ọ,
'Wọ lè máa rìn ọ̀tá rẹ.

Wò ìsun omi 'yè tí ń san
Lát' ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa,
Ó tẹ́ gbogb' ọmọ Rẹ l' ọ̀run,
Ó lé ẹ̀rù àìní lọ,
Tani yóò ṣe ààrẹ̀ b' ó bá
Ń rí irú omi bẹ́ẹ̀ mu?
Oore-ọ̀fẹ́ Olódùmarè
Kí ìyè lát' ìrandíran.

Wò iná àti ìkùúkùú
L' orí ibùgbé kọ̀ọ̀kan,
Fún ògó àt' ìdáàbòbò
Ń fi hàn wa pé O wà níhìn
'Búkún f' àwọn tí ń gbé Síónì
T' ẹ̀jẹ̀ Od' àgùtàn wẹ̀,
Jésù, Ẹni wọ́n gbékèlé,
Ti sọ wọ́n d' Ọm' Ọlọ́run

Olùgbàlà, bó O bá ka mi
Kún àwọn ara Síón,
B' ayé ń gẹ̀gàn, t' ó sì ṣàtà,
N ó s' ògó n' n Orúkọ Rẹ
Ṣíṣá l' ohun àfẹ́ ayé,
Pẹ̀lú ògó àsán rẹ̀,
Ìṣúrà tòótọ́ àt' ayọ̀
Kík' ọmọ Síónì l' ó mọ̀.