Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 33: Nínú Gbogbo Ewu Òru

In All The Dangers Of The Night

Nínú gbogbo ewu òru,
Olúwa l' ó n' ṣọ́ wa;
Àwa tún rí 'mọ́lẹ̀ òní
A tẹ ẹ̀ékún wa bá.

Olúwa pà wá mọ́ l' oní,
F' agbára Rẹ ṣọ́ wa;
Kìkì àwọn tí 'Wọ pà mọ́,
L' ó ń 'yọ nínú ewu.

K' ọ̀rọ̀ àt' ìwà wa jẹ́rìí
Pé, Tìrẹ l' àwa ń' ṣe;
Tó bẹ́ẹ̀ t' ìmọ́lẹ̀ òtítọ́,
Yóò tàn l' ojú ayé.

Má jẹ́ k' á padà lọ́dọ̀ Rẹ̀,
Olùgbàlà ọ̀wọ̀n;
Títí a ó fi ojú wa rí
Ojú Rẹ níkẹyìn.