Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 329: Jerusalem Ilé Ayọ̀
Jerusalem My Happy Home
Jerusalem ilé ayọ̀,
T' ó ṣe ọ̀wọ́n fún mi:
'Gbàwò n' 'bànújẹ́ mi yóò pín?
Tí n' ó rí ayọ̀ Rẹ?
Ògiri Rẹ ti l' ẹwà tó,
Ó l' ògó láti wò;
Ẹnu 'bodè Rẹ 'yebíye
Ìtà wúrà dídan.
Ọgbà Rẹ àt' Ọ̀nà dídan
Ni mo ti ń rò nípa;
Àwọn ohun t' ó ń tàn yìnrìn
Tí ojú kò rí rí.
Olúwa ṣe 'ránwọ́ fún wa,
K' a lè rò ń pa ọ̀run;
Títí 'wọ yóò wá mú wa lọ,
Sí paradise náà.