Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 328: Ẹ̀yin T' Ẹ Fẹ́ Olúwa
Come, We That Love The Lord
Ẹ̀yin tẹ́ e fẹ' Olúwa,
Ẹ fi ayọ̀ yìn hàn,
Ẹ jùmọ̀ kọ orin dídùn
Ẹ jùmọ̀ kọ orin dídùn
Kẹ́ ẹ sì y' ìtẹ́ náà ká,
Kẹ́ ẹ sì y' ìtẹ́ náà ká
A ń yàn lọ sí Síon,
Síon t' ó dára jùlọ,
A ń yàn gòkè lọ sí Síon,
Ìlú t' Ọlọ́run wa.
Jẹ́ k' àwọn ni máa kọ
Tí kò m' Ọlọ́run wa,
Ṣùgbọ́n àwa ọmọ Ọba,
Ṣùgbọ́n àwa ọmọ Ọba,
Yóò sọ ayọ̀ náà ká,
Yóò sọ ayọ̀ náà ká.
A ń yàn lọ sí Síon,
Síon t' ó dára jùlọ,
A ń yàn gòkè lọ sí Síon,
Ìlú t' Ọlọ́run wa.
Òkè Síónì ń mú
Ẹgbẹ̀rún adùn wá;
Kí a tó dé gbangba ọ̀run.
Kí a tó dé gbangba ọ̀run.
Pẹ̀lú ìtẹ́ wúrà,
Pẹ̀lú ìtẹ́ wúrà.
A ń yàn lọ sí Síon,
Síon t' ó dára jùlọ,
A ń yàn gòkè lọ sí Síon,
Ìlú t' Ọlọ́run wa.
Ń jẹ́ k' a máa kọrin lọ.
K' omijé gbogbo gbẹ,
A ń yàn n' ilé Immanuel
A ń yàn n' ilé Immanuel
S' ayé dídan l' òkè,
S' ayé dídan l' òkè
A ń yàn lọ sí Síon,
Síon t' ó dára jùlọ,
A ń yàn gòkè lọ sí Síon,
Ìlú t' Ọlọ́run wa.