Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 326: Àkàrà Ìyebíye Yìí
Thy Broken Body, Gracious Lord
Àkàrà iyebíye yìí,
J' àpẹẹrẹ ara Olúwa,
Ọtí wáìnì yìí dúró fún
Ẹ̀jẹ̀ Kríst t' a a tà sílẹ̀.
Nígbà tí a bá péjọ pọ̀
A ń fi 'dápọ̀ nínú Rẹ hàn,
A t' ẹ̀jẹ̀ Rẹ sílẹ̀ fún wa,
Ikú Rẹ sì dá wa n' ìdè.
A n' ìrètí pé 'Wọ yóò
L' àwọ̀sánmọ̀, t' a ó rí Ọ;
T' àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ
Yóò bá Ọ jọba títí lai