Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 324: Níhìn Mo R' Olúwa L' Ojúkojú
Here O My Lord, I See Thee Face o Face
Níhìn mo r' Olúwa l' ojúkojú,
Níhìn ni n ó f' ọwọ́ m' ohun aírí;
N ó d' oore-ọ̀fẹ́ àìlópin mu sinsin,
Èm' ó kọ gbogb' àìlera mi lé Ọ.
Níhìn n ó gbà oúnjẹ Olúwa jẹ,
N ó bá Ọ mu nínú wáìnì ọ̀run;
Níhìn ni n ó p' àníyàn ayé tì,
N ó tún mọ̀ 'yí ẹ̀ṣẹ̀ t' a a dàríjì.
Àkókò orin àt' àṣẹ ńlá dé,
Èyí l' oúnjẹ ọ̀run t' a a gbé fún mi.
Jẹ́ kí n jẹ n' nú àṣẹ yìí, k' ó sì jẹ́
Àkókò 'dápọ̀ dídùn pẹ̀lú Rẹ.