Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 322: Ọjọ́ Mímọ́, Olówó

Holy Sabbath Day Of Rest

Ọjọ́ Mímọ́, olówó,
Tí Olúwa wa búkún
Ọjọ́ tí Ọlọ́run dá
T' ó yà s' ọ̀tọ̀ f' ara Rẹ.

A! ọjọ́ 'simi mímọ́,
T' Ọlọ́run sì ti bù sí,
Yóò j' àmì fún gbogbo wa
Títí ayé àìlópin.

Máṣe, w' ayọ̀ ayé yìí
T' ó kún f' òfò àt' àsán
Ní odì kejì odò
L' ohun t' ó dára jù wá.

A! ọjọ́ 'simi mímọ́,
T' Ọlọ́run sì ti bù sí,
Yóò j' àmì fún gbogbo wa
Títí ayé àìlópin.

L' ọjọ́ 'pàlẹ̀mọ́ ọ̀sẹ̀,
B' Ìsimi tí ń sún mọ́ 'lé,
Jẹ́ kí gbogbo Kristẹ́ní
Péjọ láti yìn Jésù.

A! ọjọ́ 'simi mímọ́,
T' Ọlọ́run sì ti bù sí,
Yóò j' àmì fún gbogbo wa
Títí ayé àìlópin.

Ka bèèrè f' oore-ọ̀fẹ́,
Àt' Ìṣẹ́gun t' ó dájú,
Pé, nípa agbára Rẹ,
A ó pa ọjọ́ 'simi mọ́.

A! ọjọ́ 'simi mímọ́,
T' Ọlọ́run sì ti bù sí,
Yóò j' àmì fún gbogbo wa
Títí ayé àìlópin.