Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 321: Ọlọ́run Wa Ọ̀run

Our God in heaven

Ọlọ́run wa Ọ̀run
T' ó fi ọjọ́ mẹ́fà
Dá nkan gbogbo tí ń bẹ l' ayé
Simi n' ìjọ keje.

Ó pàṣẹ k' a bọ̀wọ̀
Fún ọjọ́ ìsimi;
Ìbínú Rẹ tóbi púpọ̀
S' àwọn t' ó rúfin yìí.

Àwọn Bàbá ńlá wa,
Ti kú nín' òkùnkùn;
Wọ́n jẹ́ ọ̀gbọ́ àbọrìṣà
Wọ́n kò mọ̀ òfin Rẹ.

Àwa dé Olúwa
Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Rẹ;
Lẹ́yìn iṣẹ́ ìjọ mẹ́fà,
Láti ṣe ìfẹ́ Rẹ.

Mímọ́ l' ọjọ́ oní,
Ó yẹ kí a simi,
Ka a péjọ nínú ilé Rẹ.
Ka gbọ́ 'rọ̀ Mímọ́ rẹ̀.

Ìsimi ńlá kan kù
F' àwọn ènìyàn Rẹ;
Ọm' Ọlọ́run, Alábùkún
Mú wa dé 'simi Rẹ.