Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 319: Ọjọ́ 'Sìn Wa Parí
Our Day of Praise Is Done
Ọjọ́ 'sìn wa parí
Ojìjì alẹ́ dé;
Ṣùgbọ́n má ṣe bá oòrùn lọ,
'Wọ ìmọ́lẹ̀ tòótọ́.
Yíká ìtẹ́ l' òkè,
Níbít' órù kò sí
Tí àwọn àfọ̀npè yìn Ọ,
Pẹ̀l' orin àìlópin.
Orin kò dùn l' ayé,
Wèrè làárẹ̀ ń mú ni;
Ṣùgbọ́n gbọ́ orin tí ọ̀run,
Báwo l' ó ti dùn tó.
Síbẹ̀, Jésù ọ̀wọ́n,
B' ó O bá t' ọkàn wa ṣe,
Àwa yóò b' àwọn ángẹ́lì
Kọ nínú orin wọn.
M' ọkàn wa dákẹ́ jẹ́ẹ́,
M' èrò àìgbọ́ràn lọ,
Sì ṣe ayé wa l' orin
T' ó l' ògó fún Oókọ Rẹ
Ní ìgbà díẹ̀ sí i,
L' òpin náà yóò dé,
T' orin èèyàn àt' ángẹ́lì,
Yóò dàpọ̀ ní ìyìn.