Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 318: Àwa Fẹ́ Ọjọ́ Rẹ
We Love Thy Sabbath Lord
Àwa fẹ́ Ọjọ́ Rẹ,
A jọ́sìn l' àṣẹ Rẹ;
F' àlàáfíà dídùn fún wa
Àt' ìjìnlẹ̀ 'gbàgbọ́.
Ángẹ́lì hó f' ayọ̀
Láti r' iṣẹ́ ẹ̀dá;
Àwa náà yóò gb' ohùn s' òkè
L' orin ìyìn sí Ọ.
Ìyìn fún 'fẹ́ ńlá Rẹ
Èdìdì f' ọjọ́ yìí,
Àmín kí gbogbo wa lè mọ̀
Pé tiwa n' ìjọba Rẹ.
Ọba ńlá Ẹlẹ́dá,
Nípa oore-ọ̀fẹ́ Rẹ,
Y' ọkàn wa sí mímọ́ sì jẹ́
K' a a lè rí ojú Rẹ.
Pẹ̀lú àwọn mímọ́
Lórí òkè Síón,
K' a a lè máa kọrin
Ọjọ́ Rẹ títí ayérayé.