Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 317: Olùgbàlà A Gb' Ohùn Wa S' Òkè

Saviour Again To Thy Dear Name

Olùgbàlà a gb' ohùn wa s' òkè,
Pẹ̀lú ìṣọ̀kan l' orin ìpínyà;
A wá yìn Ọ k' a a tó par' ìsìn wa,
Àwa dúró n' ìrẹ̀lẹ̀ f' ọ̀rọ̀ Rẹ.

F' àlàáfíà fún wa b' a tí ń rè 'lé;
Ìwọ n' 'bẹ̀rẹ̀ oùn 'parí ọjọ́ wa;
Má jẹ́ k' a ṣe l' ọkàn àt' etè wa
T' a fi ń p' oókọ Rẹ nínú ilé yí.

Jésù f' àlàáfíà fún wa l' órù,
Bá wa sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀
P' àwọn ọmọ Rẹ mọ́ n' inú ibi,
Bákan l' ọ̀sán àt' órù l' ọ̀dọ̀ Rẹ.

Fún wa ní àlàáfíà l' ayé wa,
Ìtúrà wa àt' Olùgbèjà wa;
Gbàt' ohùn Rẹ bá mú 'yọ̀nú parí
F' àlàáfíà àìlópin ṣe ti wa.