Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 316: Ọjọ́ 'Simi Àt' Ayọ̀ Ọjọ́ Inú Dídùn

O Day Of Rest And Gladness

Ọjọ́ 'simi àt' ayọ̀
Ọjọ́ inú dídùn,
Ìwòsàn fún 'bànùjẹ́,
Ọjọ́ dídáa jùlọ,
Tí àwọn ẹni gíga,
Ń wọ́lẹ̀ ń wájú 'tẹ́ Rẹ,
Ń kọ mímọ́, mímọ́, mímọ́,
S' Ẹni Mẹ́tàlọ́kan.

Èbúté ààbò ni o
Fún 'jì t' ó ń ja yíká
Ọgbà 'bomi rìn ni o,
Pẹ̀l' omi Paradais;
Orísun 'túrà ni o,
L' ayé àginjù yìí,
Lórí rẹ̀ b' òkè Písgà
L' a ń wò 'lẹ̀ ìlérí.

Ọjọ́ ìronú dídùn
Ọjọ́ ìfẹ́ mímọ́,
Ọjọ́ àjíǹdé láti
Ayé, sí nkan t' ọ̀run;
K' a r' oore-ọ̀fẹ́ títun,
L' ọjọ́ 'simi wa yìí,
A ń rètí 'simi t' ó kù
F' àwọn alábùkún.