Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 313: Ọjọ́ Dídùn
Delightful Day
Ọjọ́ dídùn, ẹ̀bùn t' ọ̀run
T' a a f' ènìyàn l' ọgbà Eden;
Ọjọ́ t' Olúwa fífún ni,
Kí ẹ̀dá Rẹ lè r' ìbùkún.
Ìrántí Ọba Ẹlẹ́dá,
A fi ayọ̀ kí Ọ káàbọ̀
'Gbà t' a a kójọ láti yìn Ọ,
Ọkàn gbogbo wa kún f' ayọ̀.
F' ìyìn fún Jésù, Ẹni tí
Ó f' ẹ̀jẹ̀ Rẹ rà wa padà;
F' ògo fún Ọmọ Ọlọ́run,
Yìn ín, ẹ̀yin ẹ̀dá t' ó l' ẹ̀mí
Nípa ẹ̀ṣẹ̀ l' a wọ 'bínú,
Ó kú fún wa kí Òun lè fà
Aṣako ẹ̀ṣẹ̀ wa s' ọ̀nà
K' a a lè p' òfin Ọlọ́run mọ́.
Òfin náà yóò máa j' ayọ̀ wa
Ọjọ́ 'simi j' apá kan rẹ̀
'Gbà t' a a bá jogún ayé ni,
Gbogbo ẹ̀dá yóò máa pàá mọ́.