Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 312: Olúwa Ọjọ́-ìsimi

Lord Of The Sabbath Hear Us Pray

Olúwa Ọjọ́-ìsimi,
Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa níhìn, lónìí;
Gbà orin ìyìn tí a ń kọ,
Bí ẹbọ ọpẹ́ wa sí Ọ.

A fẹ́ ìsimi t' ayé yìí;
Ṣùgbọ́n 'simi t' ọ̀run dùn jù;
Èyí náà l' ọkàn wa ń lépà,
Pẹ̀lú ìtara oùn ìfẹ́.

Kò s' ààrẹ̀ mọ́, tàb' ìpónjú
Ẹ̀ṣẹ̀ tàb' ikú k' yóò dé bẹ̀;
Ẹkún kì yóò dà mọ́ orin
Tí àwọn ẹni-àìkú ń kọ.

Kò sí ìdàgírí ọ̀tá;
Bẹ́ẹ̀ ni kò s' ìpáyà níbẹ̀;
Kò sí órù, kò s' ìkùúkùú,
Àfi ọ̀sán títí láéláé.

Máa bọ̀ ọjọ́ t' a ti ń rètí
Là s' ayé ẹ̀ṣẹ̀ oùn òsì;
Ó wù mí kí n f' ayé sílẹ̀,
Fún 'simi l' ọ̀dọ̀ Ọlọ́run