Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 310: Ọ̀sẹ̀ Kan Tún Kọjá Lọ

Safety Through Another Week

Ọ̀sẹ̀ kan tún kọjá lọ,
Bàbá m' ẹ̀mí wa là a jà:
A d' rọ̀ n' ọgbà Rẹ lónìí,
Láti gbà 'búkún ọ̀tún;
Ọjọ́ tó dára jù
Àmín ìsimi láéláé.
Ọjọ́ tí ó dára jù
Àmín ìsimi láéláé.

B' a tí ń wá oore-ọ̀fẹ́,
Nípa Oókọ Olúwa;
F' ojú ìbàrẹ́ Rẹ hàn,
M' ẹ̀ṣẹ̀ àt' ẹ̀gàn wa lọ,
A p' àníyàn ayé tì,
Ń simi lónì pẹ̀lú Rẹ
A p' àníyàn ayé tì,
Ń simi lónì pẹ̀lú Rẹ.

Gbà t' a a jí sí 'mọ́lẹ̀ Rẹ
Jẹ́ k' a a mọ̀ p' O wà níhìn;
Kí ògo Rẹ padé wa,
B' a tí wà n' ilé Rẹ yìí;
Níhìn jẹ́ k' a n' ìtọwọ́,
Oúnjẹ wa àìnípẹ̀kun.
Níhìn jẹ́ k' a n' ìtọwọ́,
Oúnjẹ wa àìnípẹ̀kun.

K' ìhìn náà ṣẹ́gun ẹ̀ṣẹ̀,
K' ó tú àwọn mímọ́ n' nú;
K' èso oore-ọ̀fẹ́ pọ̀ sí i,
Mú gbogbo àrùn wa sàn;
Bẹ́ẹ̀ ni k' ìsimi wa rí,
D' ọjọ́ t' a ó bá Ọ jọba,
Bẹ́ẹ̀ ni k' ìsimi wa rí,
D' ọjọ́ t' a ó bá Ọ jọba.