Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 31: Wá S' Àdúrà Oòrọ̀
Come To the Morning Prayer
Wá s' àdúrà oòrọ̀
Kúnlẹ̀ ká a gbàdúrà;
Àdúrà ni ọ̀pá kristẹ́n
Láti b' Ọlọ́run rìn.
Lọ́sán, wolé lábẹ́
Àpàt' ayérayé
Ìtùrà ojìjì Rẹ̀ dùn
Nígbà t' oòrùn bá mú.
Jẹ́ kí gbogbo ilé
Wá gbàdúrà l' alẹ́;
Kí ilé wa di t' Ọlọ́run
Àti 'bodè ọ̀run.
Nígbà t' ó d' òganjọ́,
Jẹ́ k' á wí l' ẹ̀mí, pé
Mo sùn, ṣùgbọ́n ọkàn mi jí
Láti bá Ọ ṣọ́nà.