Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 307: Olúwa Àwa 'Ránṣẹ́ Rẹ

With Glad Thanksgiving Gracious Lord

Olúwa àwa 'ránṣẹ́ Rẹ,
Péjọ pẹ̀lú ọpẹ́ lónìí,
A fi 'rẹ̀lẹ̀ wọlé fún Ọ,
Láti gbà àṣẹ Rẹ l' ọ̀tún.

A dúpẹ́ fún irúgbìn t' ó
Mú 'ṣe odòdó yìí bẹ̀rẹ̀,
A yìn Ọ fún igi náà tí
Ẹ̀ka rẹ̀ tàn ká àgbáyé.

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ f' àwọn
T' ó n' ìgbàgbọ́ àt' ìpinnu,
Tí wọ́n fi 'pìlẹ̀ náà lé 'lẹ̀
'Tí wọ́n ṣa gbogbo ìpàá wọn.

A dúpẹ́ f' ọ̀pọ̀ ọdún yìí,
Tí 'ṣe ń dàgbà t' ó sì ń gbòòrò,
Àti fún ìtọ́sọ́nà t' ó
Mú wa j' olóòótọ́ s' Ọlọ́run.

Jésù ọ̀wọ́n, a tọ Ọ wá
"S' àpákan" gẹ́gẹ́ b' àṣẹ Rẹ
Láti yìn Ọ f' èso t' a a rí
K' a sì bẹ Ọ fún àìní wa.