Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 306: Tú Ẹ̀mí Rẹ Lát' Òkè Wá

Pour Out Thy Spirit From on High

Tú Ẹ̀mí Rẹ lát' òkè wá,
Jésù búkún àpéjọ wa;
Fún gbogbo wa l' oore-ọ̀fẹ́
Sì f' aṣọ odòdó wọ̀ wa.

Fún wa l' ọgbọ́n lát' òkè wá,
Ìtara, 'gbàgbọ́, oùn 'rẹ̀lẹ̀,
Jẹ́ k' a fẹ́ àwọn tó O fẹ́ràn,
K' ìfẹ́ wọn lè máa gb' ọkàn wa.

K' a má ṣààrẹ̀ nín' àdúrà,
K' a sì máa ṣọ́nà n' gbà gbogbo;
K' a lè kìlọ̀ fún ẹlẹ́ṣẹ̀,
K' a sì máa bọ́ àgùtàn Rẹ.

'Gbà 'ṣe wa ní 'hìn-in bá parí,
Ní Ìrètí pẹ̀lú 'rẹ̀lẹ̀,
'Gbàt' Olùṣ'-àgùtàn bá yọ,
Jésù jẹ́ k' a jọ jẹ́ Tire.