Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 305: Ìwọ Y' Ara Rẹ Sí Mímọ́
Thou Who Thyself Didst Sanctify
Ìwọ y' ara Rẹ sí mímọ́,
'Wọ y' ara Rẹ s' ọ̀tọ̀;
F' ọwọ́ s' ẹ̀rọ ìránṣẹ́ Rẹ
Àn' ẹ̀rọ ọkàn rẹ̀.
Tọwọ́tọwọ́ ni òun náà yóò
D' ọmọ ogun tòótọ́
Yóò ṣe iṣẹ́ Rẹ t' ó l' ògó
Nínú papa ayé.
Jésù jọ̀wọ́ gbà oókọ rẹ̀;
Sì jẹ́ kí ó lè ní
Iná ìyè ní lát' ọ̀run
Tí ó ń jó l' ọkàn rẹ̀.
Fi ìhàmọ́ra ìmọ́lẹ̀
Àti t' ìgboyà fún un
Láti ja ogun yìí, k' ó sì
Ṣe olóòótọ́ d' òpin!
Olúwa, ẹni bá ṣẹ́gun
Yóò ní 'ràwọ̀ oòrọ̀,
Ẹ̀wù àt' ìmọ̀ ìṣẹ́gun,
Àti adé ìyè.