Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 303: Ìwọ Ẹni T' Ọwọ́ Rẹ Mú Wa D' Ọjọ́ Oní
O Thou Whose Hand Hath Brought Us
Ìwọ Ẹni t' ọwọ́ Rẹ
Mú wa d' ọjọ́ oní,
Jọ̀wọ́ tẹ́wọ́ gb' ọpẹ́ wa,
Fẹ́tí s' àdúrà wa;
Kí ìmúrasílẹ̀ wa
Fún ìsìn oní jẹ́
Láti f' ara wa fún Ọ,
Pẹ̀l' ọkàn ìṣọ̀kan.
A yìn Ọ fún ilé yìí,
Tí a kọ́ l' àṣẹ Rẹ,
F' olúkúlùkù ọkàn
Àti ọwọ́ ìfẹ́;
Jẹ́ k' a lè rí ògo Rẹ
Nínú Tẹ́mpìlì Rẹ
'Tòrí gbogbo ẹwà rẹ
Kò jẹ́ nkan láìsí Rẹ.
Nígbà t' a a bá sì péjọ,
Láti jọ́sìn fún Ọ,
F' agbára òtítọ́ hàn,
K' àdúrà sì 'gòkè
K' ẹni tí ń ṣàápọ̀n l' ayé
Dìde sí nkan t' ọ̀run,
Kí gbogb' ènìyàn kọ́ 'fẹ́ Rẹ,
Fún gbogbo wa l' okùn.
B' ọdún tí ń yí l' ọdún,
Tí ìfẹ́ sì ń dàgbà,
Tí a bá wá s' ilé yìí
Láti ṣe 'rántí rẹ̀
Kí ọlá títóbi rẹ̀
Àt' ògo rẹ̀ láéláé
Lè mú ọ̀pọ̀ ènìyàn
R' ọ̀nà dé ọ̀dọ̀ Rẹ.