Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 302: A Gbọ́ Tiwa Ẹn' Àìlópin!
O Bow Thine Ear, Eternal One
A gbọ́ tiwa Ẹn' Àìlópin!
Ìwọ ni gbogb' ọkàn ń ké pè;
Àwọn atẹ̀lé Ọmọ Rẹ
Kó 'lé yìí wọn sí fífún Ọ.
Jẹ́ k' a p' Ọjọ́ rẹ mọ́ níbẹ̀,
K' a lọ ilé yìí fún 'sìn Rẹ,
Bí ilé tí Jákọ́bù sùn,
'Lé Ọlọ́run, bodè ọ̀run.
Jẹ́, k' ọlá Rẹ wà n' bẹ̀, sì jẹ́
K' àdúrà àwọn ọmọ Rẹ
Lát' inú ọkàn tòótọ́ wá,
Gòkè lọ b' ẹbọ tùràrí.