Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 300: A! Olùkórè Èmi
Ho! Reapers of Life's Harvest
A! olùkórè èmi,
Ẹ ṣe ń dúró lásán,
T' ojìj' alẹ́ ń yí yín ká,
T' ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sù?
Ẹ̀ṣe tí ẹ fi ń w' ọ̀nà
F' olùkórè míràn,
Àárọ̀ ń yára lọ kankan;
Ẹ̀ṣe t' ẹ fi ń ṣ' ọ̀lẹ?
Ẹ fi dọ̀jẹ́ mímú yín
Ṣe 'kórè ọkà náà;
Alẹ́ ń yára bọ̀ kankan,
Yóò sì tún dé láìpẹ́;
Olúwa ń p' olùkórè
Yóò ha pè lásán bí?
Ó ha yẹ kí ọkà náà
Ṣòfò s' inú oko?
Sọ̀kalẹ̀ lát' òkè wá,
Pẹ̀lú 'tara ọkàn,
Bẹ́ẹ̀ni k' ó má jàfàrà,
'Tòr' ọ̀sán fẹ́rẹ̀ pọn
Wá pẹ̀lú agbára rẹ,
Bẹ́ẹ̀ni k' ó má ṣààrẹ̀
Má dúró títí alẹ́
Yóò fi m' ọrọ̀ rẹ wá.
Gun òkè láti l' ọgbọ́n,
Pa gbogb' àṣìṣe rẹ;
Máṣe f' ìmọ̀ rẹ pamọ́,
K' ènìyàn bàá lè mọ̀;
J' Olóòótọ́ n' nú iṣẹ́ rẹ,
N' iṣẹ́ Olúwa rẹ,
Láìpẹ́ li adé wúrà,
Yóò sì jẹ́ ère rẹ.