Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 3: Ọkàn Mi, Yìn Ọba Ọ̀run

Praise, My Soul, the King of Heaven

Ọkàn mi, yìn Ọba ọ̀run,
M' ọre rẹ wa s' ọ̀dọ̀ Rẹ̀;
'Wo tá a wò san tá a dáríjì
Tal' o bá hà yìn bí Rẹ?
Yìn Oluwa, aleluya
Yìn Ọba aìnípẹ́kun.

Yìn In fún àánú Rẹ̀ sí àwọn
Baba wa, n' nú 'pọnjú wọn;
Yìn In, ọkàn náà ní títí,
O lọra láti bínú;
Yìn Oluwa, aleluya
Òlógò n' nú òtítọ́.

Bí baba ni o ń tọ́jú wa,
Ó sì mọ àìlera wa
Jẹjẹ l' Ó ń gbé wa l' àpá Rẹ̀
Ó ń gbà wá lọ́wọ́ ọ̀tá;
Yìn Oluwa, aleluya
Àánú Rẹ̀ yì ayé ká.

Ẹ̀yin angẹl', ẹ júbà Rẹ̀;
Ẹ̀yin ń rí I lójúkoojú;
Oòrùn òṣùpá, ẹ wólẹ̀,
Àti gbogbo àgbáyé
Ẹ bá wa yìn In aleluya
Ọlọrun Oloor' ọ̀fẹ́.