Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 299: Fúnrúgbìn L' Òwúrọ̀
Sowing in the Morning
Fúnrúgbìn l' òwúrọ̀,
Fúnrúgbìn oore,
Fúnrúgbìn ní ọ̀sán, àti lój' alẹ́;
Máa rètí ìkórè àt' ìgbà ìkójọ,
Àwa yóò sì f' ayọ̀ rù ìtí wọ 'lé.
Rù ìtí wọ 'lé, Rù ìtí wọ 'lé,
Àwa yóò sì f' ayọ̀ rù ìtí wọ 'lé
Rù ìtí wọ 'lé, rù ìtí wọ 'lé
Àwa yóò sì f' ayọ̀ rù ìtí wọ 'lé.
Fún irúgbìn n' nú oòrùn
Fúnrúgbìn n' ìbòjì
Máṣe bẹ̀rù sánmà, tàbí òtútù;
'Gbàt' ìkórè àti làálàá bá sì parí.
Àwa yóò sì f' ayọ̀ rù ìtí wọ 'lé.
Rù ìtí wọ 'lé, Rù ìtí wọ 'lé,
Àwa yóò sì f' ayọ̀ rù ìtí wọ 'lé
Rù ìtí wọ 'lé, rù ìtí wọ 'lé
Àwa yóò sì f' ayọ̀ rù ìtí wọ 'lé.
F' omijé fúnrúgbìn,
Fúnrúgbìn f' Olúwa,
B' àdánù t' a ń rí ń m' ẹ̀dùn wa n' gbagbogbo,
Ní òpin ẹkún wa, Òun yóò kí wa káàbọ̀
Àwa yóò sì f' ayọ̀ rù ìtí wọ 'lé.
Rù ìtí wọ 'lé, Rù ìtí wọ 'lé,
Àwa yóò sì f' ayọ̀ rù ìtí wọ 'lé
Rù ìtí wọ 'lé, rù ìtí wọ 'lé
Àwa yóò sì f' ayọ̀ rù ìtí wọ 'lé.