Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 298: Fún Irúgbìn Ní Kùtùkùtù
Sowing The Seed By The Daylight Fair
Fún irúgbìn ní kùtùkùtù,
Fún irúgbìn ní ọ̀sán gangan,
Fún irúgbìn ní ojú alẹ́,
Fún irúgbìn ní órù gànjọ́;
A! kín ni 'kórè yóò jẹ́?
Ohun t' a gbìn l' òkùnkùn tàbí ní 'mọ́lẹ̀,
Ní àìlera tàbí ní agbára,
A ó kórè rẹ̀ l' ayé tàbí l' ọ̀run,
Dájúdájú n' ìkórè rẹ̀ yóò jẹ́!
Fún irúgbìn sí ẹ̀bá ọ̀nà
Fún irúgbìn s' orí àpáta
Fún irúgbìn sí àárín ẹ̀gún,
Fún irúgbìn sí ilẹ̀ rere,
A! kín ni 'kórè yóò jẹ́?
Ohun t' a gbìn l' òkùnkùn tàbí ní 'mọ́lẹ̀,
Ní àìlera tàbí ní agbára,
A ó kórè rẹ̀ l' ayé tàbí l' ọ̀run,
Dájúdájú n' ìkórè rẹ̀ yóò jẹ́!
Fún irúgbìn ọ̀pọ̀ ìrora,
Fún irúgbìn aláìníronú;
Fún irúgbìn ìwà-ìbàjẹ́,
Fún irúgbìn 'tìjú àìlópin;
A! kín ni 'kórè yóò jẹ́?
Ohun t' a gbìn l' òkùnkùn tàbí ní 'mọ́lẹ̀,
Ní àìlera tàbí ní agbára,
A ó kórè rẹ̀ l' ayé tàbí l' ọ̀run,
Dájúdájú n' ìkórè rẹ̀ yóò jẹ́!
Fún irúgbìn pẹ̀lú 'bànújẹ́,
Fún irúgbìn 'gbà t' ẹkún ń gbọ̀n ní,
Tít' Olùkórè yóò f' ayọ̀ dé,
A! kín ni 'kórè yóò jẹ́?
Ohun t' a gbìn l' òkùnkùn tàbí ní 'mọ́lẹ̀,
Ní àìlera tàbí ní agbára,
A ó kórè rẹ̀ l' ayé tàbí l' ọ̀run,
Dájúdájú n' ìkórè rẹ̀ yóò jẹ́!