Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 297: Àwọn Olùkórè Dà?

Oh Where Are The Reapers?

Àwọn olùkórè dà, tí yóò kó
Àlìkámà kúrò l' oko ẹ̀ṣẹ̀?
Pẹ̀l' odòdó - l' a ó ṣe iṣẹ́ náà,
Ìsimi kò sí títí yóò fi tán.

Olùkórè dà? Tani yóò wá
Láti bá wa yọ ayọ̀ ìkórè náà?
Tani yóò wá láti bá wa kó
Àlìkámà kúrò l' oko ẹ̀ṣẹ̀?

Ṣàá wòó, ire oko gbogbo ti pọn
Ayé sì ń dúró dé ìkórè náà;
Ṣùgbọ́n àwọn aláàgbàṣe kò tó
Pẹ̀lú ìlọ̀ra, ọ̀pọ̀ yóò ṣègbé.

Olùkórè dà? Tani yóò wá
Láti bá wa yọ ayọ̀ ìkórè náà?
Tani yóò wá láti bá wa kó
Àlìkámà kúrò l' oko ẹ̀ṣẹ̀?

Ọm' èè 'yàn ẹ wá pẹ̀lú 'dọ̀jẹ́,
Ẹ sì wá kó ire ìyebíye;
Láìpẹ́ Olúwa ìkórè yóò dé,
Láti fún yín ní ayọ̀ ìkórè.

Olùkórè dà? Tani yóò wá
Láti bá wa yọ ayọ̀ ìkórè náà?
Tani yóò wá láti bá wa kó
Àlìkámà kúrò l' oko ẹ̀ṣẹ̀?