Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 296: M' Òótọ́ Rẹ Yára Olúwa
Speed On Thy Truth Eternal One
M' òótọ́ Rẹ yára Olúwa,
Sì kédé òfin Rẹ,
Títí olúkúlùkù èèyàn
Yóò fi gb' oókọ Jésù
Agbára 'jọba Rẹ n' tiwa,
A wọlé ń wájú Rẹ.
L' àkókò yìí láti yìn Ọ,
Ọlọ́run tí kì í kú.
Ọlọ́run tí kì í yí padà,
Òótọ́ Rẹ wà láéláé
B' a tilẹ̀ ń tẹ̀ ẹ níbi gbogbo,
Tí ẹ̀ṣẹ̀ gbé ń jọba,
Ẹ dìde, k' ẹ sì tàn 'mọ́lẹ̀,
Ẹ̀yin díẹ̀ t' a a yàn;
Kò sí iṣẹ́ tó l' ọlá bíi
Iṣẹ́ t' a fi fún yín
A fẹ́rẹ̀ dé àkókò náà
Tí 'kú kì yóò sí mọ́,
Tí yóò mú simi b' aláàrẹ̀,
Tí ọ̀run yóò sọ̀kalẹ̀
Jí dìde, k' ẹ sì tàn 'mọ́lẹ̀;
Kédé òtítọ́ Rẹ
'Ṣe Jésù àti tire ni,
'Wọ 'ránṣẹ́ Ọlọ́run.
A yìn Ọba ayérayé
A kédé òótọ́ Rẹ,
Àṣẹ Rẹ b' idà àt' àsà;
Ọ̀rọ̀ Rẹ bí iná,
B' ọdún bá ti ń yí l' ọdún
Àti títí ayé
A ó wọlé f' àṣẹ jẹ̀jẹ̀ Rẹ,
Àwa ó sì sìn Ọ.