Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 295: T' Ayọ̀, T' Ayọ̀ L' A Ó Ṣiṣẹ́ Jésù
Gladly, Gladly, Toiling For The Master
T' ayọ̀, t' ayọ̀ l' a ó ṣiṣẹ́ Jésù,
Pẹ̀lú ọwọ́ àt' ọkàn ìfẹ́;
Iṣẹ́kiṣẹ́ t' O yàn sílẹ̀ fún wa,
A ó máa f' ìfẹ́ ṣa ipa tiwa.
Iṣẹ́ fún Jésù,
T' ère t' ayọ̀ ni,
A ó máa f' ayọ̀ ṣe
Iṣẹ́ fún Jésù, nín' ọgbà Rẹ níhìn yìí.
T' ayọ̀, t' ayọ̀ là ó máa sọ ìtàn náà.
T' ìfẹ́ Jésù sí gbogb' àgbáyé;
Kríst' ìmọ́lẹ̀ dídan ògo Bàbá
Yóò fi ìfẹ́ fún wa n' ìbùkún.
Iṣẹ́ fún Jésù,
T' ère t' ayọ̀ ni,
A ó máa f' ayọ̀ ṣe
Iṣẹ́ fún Jésù, nín' ọgbà Rẹ níhìn yìí.
Ní ìrẹ̀lẹ̀ là ó máa tẹ̀lé Jésù
A ó f' odòdó rìn ní ọ̀nà Rẹ;
Mú alárìnkiri s' ọ̀nà Jésù,
Tọ́ka ẹlẹ́ṣẹ̀ s' Od' àgùtàn.
Iṣẹ́ fún Jésù,
T' ère t' ayọ̀ ni,
A ó máa f' ayọ̀ ṣe
Iṣẹ́ fún Jésù, nín' ọgbà Rẹ níhìn yìí.