Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 294: Gbọ́ Ohùn Olùṣ' Àgùtàn
Hark! 'Tis The Shepherd's Voice I Hear
Gbọ́ ohùn Olùṣ'-àgùtàn,
Jìnà rere s' ayé ẹ̀ṣẹ̀;
Ó ń p' àgùtàn tí ń ṣonù lọ,
Kúrò l' àgb' Olùṣ'-àgùtàn
Mú wọn wá, mú wọn wá
Mú wọn kúrò nín' oko ẹ̀ṣẹ̀;
Mú wọn wá, mú wọn wá,
Mú aṣako wá fún Jésù.
Tani yóò lọ ṣe 'ránwọ́ fún-Un?
Láti wá àwọn aṣako;
Tani yóò mú wọn wá s' ilé
Kúrò nín' òtútù ẹ̀ṣẹ̀?
Mú wọn wá, mú wọn wá
Mú wọn kúrò nín' oko ẹ̀ṣẹ̀;
Mú wọn wá, mú wọn wá,
Mú aṣako wá fún Jésù.
Gbọ́ 'ráhùn wọn nínú ijù,
Lórí òkè palapala,
Gbọ́, Olúwa ń sọ fún ọ pé;
Lọ w' àgùtàn mi l' àwárí.
Mú wọn wá, mú wọn wá
Mú wọn kúrò nín' oko ẹ̀ṣẹ̀;
Mú wọn wá, mú wọn wá,
Mú aṣako wá fún Jésù.