Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 293: Kín Ni Kí N Ṣe F' Olùgbàlà Mi?

What Shall I Do For Christ My Saviour

Kín ni kí n ṣe f' Olùgbàlà mi?
N ó ṣe san gbèsè tí mo jẹ́ Ẹ?
Ó dà mí ń dé k' rọ̀ l' oko ẹrú
N ó ṣe lè fi ìfẹ́ mi hàn?

Èyí ni n ó ṣe f' Olùgbàlà mi,
Èyí yóò fi ìfẹ́ mi hàn?
N ó sọ t' oore Rẹ, n ó sọ t' àánú Rẹ,
N ó rìn l' ọ̀nà Rẹ l' ayé yìí

N ó sọ fún-un pé mo ti ń ṣako lọ;
N ó bẹ̀bẹ̀ k' Ó gbà mí padà;
N ó tọrọ 'dàríjì lọ́wọ́ Rẹ
N ó bẹ̀bẹ̀ k' ó w' ẹ̀ṣẹ̀ mi nù.

Èyí ni n ó ṣe f' Olùgbàlà mi,
Èyí yóò fi ìfẹ́ mi hàn?
N ó sọ t' oore Rẹ, n ó sọ t' àánú Rẹ,
N ó rìn l' ọ̀nà Rẹ l' ayé yìí

'Gbà náà n ó mú Bíbélì mímọ́,
Láti máa wá òtítọ́ Rẹ
Kí n bàá lè tọ́ elòmíì s' ọ̀nà,
Jésù t' Ó kọ́kọ́ fẹ́ràn mi.

Èyí ni n ó ṣe f' Olùgbàlà mi,
Èyí yóò fi ìfẹ́ mi hàn?
N ó sọ t' oore Rẹ, n ó sọ t' àánú Rẹ,
N ó rìn l' ọ̀nà Rẹ l' ayé yìí