Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 292: Olúwa, 'Bití Mo Bá Wà

Just Where I Am

Olúwa, 'bití mo bá wà,
Kí n s' ẹlẹ́rìí tòótọ́ fún Ọ
'Gbà àwọn míì ń wá bí t' ó san
Ṣe mi l' olóòótọ́ níhìn yìí.

Ọ̀nà 'bití mo wà kò dán,
Ṣùgbọ́n ìwọ wà pẹ̀lú mi;
Àwọn t' ó bá Ọ rìn simi
Fún mi l' okùn, kí n sì gbé jẹẹ.

Olúwa, bó O tọ́ka mi sí,
Ilẹ̀ tí ó jìnà rere
T' ìmọ́lẹ̀ ọ̀run kò sí sí,
Jẹ́ k' èmi lọ ròhìn Krístì.

Bó O bá sì ní kí n d' rọ̀ ní 'lé,
Jẹ́ kí èmi tún ọ̀nà ṣe
Fún àwọn tí ó lọ ṣiṣẹ́
Tí wọ́n fi 'lé oùn ore 'lẹ̀.

'Bí tí mo wà jẹ́ kí n jèrè
Ọkàn tí kò sí 'rètí fún,
Pẹ̀lú ìtara gbígbóná,
Fún mi l' agbára láti lọ.