Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 291: Máa Ṣiṣẹ́ Lọ

Go Labour On

Máa ṣiṣẹ́ lọ, nígbà ọ̀sán,
Órù ayé yìí fẹ́rẹ̀ dé;
Múra s' iṣẹ́ máṣe s' ọ̀lẹ
Kí o bá lè gbà ọkàn là

Ọgọ́lọ́gọ̀ l' àwọn t' ó ń kú
Láìní ìrètí àjíǹdé,
Tàn 'mọ́lẹ̀ náà kárí ayé
Kí òkùnkùn lè d' ìmọ́lẹ̀.

Máa ṣiṣẹ́ lọ, Máa gbàdúrà;
F' ọgbọ́n wá àwọn t' ó ṣìn;
Jáde lọ s' ọ̀pọ̀pọ̀ ọ̀nà,
Rò aṣako láti wọ 'lé.

Máa ṣiṣẹ́ lọ, b' ààrẹ̀ tilẹ̀
Mú ọwọ́ àti ẹ̀ẹ́kún rẹ;
Tẹ́ 'ra mọ́ 'ṣe ère rẹ ni
Ìjọba àt' adé ògo.