Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 290: Gbọ́ Ohùn Jésù Tí Ń Ké Pé
Hark! The Voice Of Jesus Calling
Gbọ́ ohùn Jésù tí ń ké pé
Tani yóò ṣiṣẹ́ lónìí?
Oko pọn púpọ̀ fún 'kórè;
Tani yóò lọ kó o wá 'lé
Kíkan kíkan l' Olúwa ń pè,
Ẹ̀bùn ńlá ni yóò fún ọ;
Tani yóò fi ayọ̀ dáhùn?
Pé Èmi ni yìí ràn mi!
B' ìwọ kò lè la òkun lọ,
Láti w' àwọn kèèfèrí,
O lè rí wọn nítòsí rẹ,
Wọ́n wà l' ẹnu-ọ̀nà rẹ
Bó o kò lè sọ̀rọ̀ b' ángẹ́lì,
Bó o kò lè ṣe bí ti Paul,
'Wọ lè jẹ́rí ìfẹ́ Jésù
Pé, Ó kú fún gbogbo wa.
B' ìwọ kò lè ṣe alọ́rẹ,
Lórí odì Síónì,
Láti tọ́ka s' ọ̀nà ọ̀run,
Láti f' ìyè lọ ẹ̀dá,
'Wọ lè f' àdúrà àt' ore
Ṣe ohun t' Ọlọ́run wí;
'Wọ lè se gẹ́gẹ́ bí Aaron
T' ó gb' ọwọ́ wòlíì s' òkè.
Nígbà t' ẹ̀mí ènìyàn ń kú,
Tí Olúwa sì ń pè ọ,
Má jẹ́ k' a gbọ́, kí o wí pé
Kò sí nkan t' èmi lè ṣe!
F' ayọ̀ gbà iṣẹ́ t' Ó ràn ọ
F' iṣẹ́ Rẹ ṣe ayọ̀ rẹ;
'Gbàt' Ó ń pè ọ, tara dáhùn
Pé, èmi ni yìí, ràn mi!