Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 29: Wá S' Ọ̀dọ̀ Mi, Olúwa Mi, Ní Kùtùkùtù Òwúrọ̀

Come To me, Lord, When First I Wake

Wá s' ọ̀dọ̀ mi, Olúwa mi,
Ní kùtùkùtù òwúrọ̀;
Mú k' èrò sọ jáde,
Lát' inú mi sókè ọ̀run.

Wá s' ọ̀dọ̀ mi, Olúwa mi,
Ní wákàtí ọ̀sán gangan;
Kí 'yọ̀nú má bá ṣe mi mọ́
Wọ́n á sì s' ọ̀sán mi d' òru.

Wá s' ọ̀dọ̀ mi, Olúwa mi,
Nígbàtí alẹ́ bá ń lẹ lọ;
Bí ọkàn mi bá ń ṣákò lọ,
Mú u padà' f' ojú 'rẹ wò mí.